ORIN DAFIDI 141

Adura Ààbò

1 OLUWA, mo ké pè ọ́, tètè wá dá mi lóhùn,

tẹ́tí sí ohùn mi nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.

2 Jẹ́ kí adura mi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ bíi turari,

sì jẹ́ kí ọwọ́ adura tí mo gbé sókè dàbí ẹbọ àṣáálẹ́.

3 OLUWA, fi ìjánu sí mi ní ẹnu,

sì ṣe aṣọ́nà ètè mi.

4 Má jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ibi, má sì jẹ́ kí n lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìkà.

Má jẹ́ kí n bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rìn pọ̀,

má sì jẹ́ kí n jẹ ninu oúnjẹ àdídùn wọn.

5 N ò kọ̀ kí ẹni rere bá mi wí,

n ò kọ̀ kí ó nà mí;

kí ó ṣá ti fi ìfẹ́ bá mi wí.

Ṣugbọn má jẹ́ kí eniyan burúkú tilẹ̀ ta òróró sí mi lórí,

nítorí pé nígbàkúùgbà ni mò ń fi adura tako ìwà ibi wọn.

6 Nígbà tí ọwọ́ àwọn tí yóo dá wọn lẹ́bi bá tẹ̀ wọ́n,

wọn óo gbà pé, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLUWA.

7 Bí òkúta tí eniyan là, tí ó fọ́ yángá-yángá sílẹ̀,

ni a óo fọ́n egungun wọn ká sí ẹnu ibojì.

8 Ṣugbọn ìwọ ni mo gbójúlé, OLUWA, Ọlọrun.

Ìwọ ni asà mi,

má fi mí sílẹ̀ láìní ààbò.

9 Pa mí mọ́ ninu ewu tàkúté,

ati ti okùn tí àwọn aṣebi dẹ sílẹ̀ dè mí.

10 Jẹ́ kí àwọn eniyan burúkú ṣubú sinu àwọ̀n ara wọn,

kí èmi sì lọ láìfarapa.