ÌFIHÀN 5

Ìwé Kíká ati Ọ̀dọ́ Aguntan

1 Lẹ́yìn náà, mo rí ìwé kan ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́: wọ́n kọ nǹkan sí i ninu ati lóde, wọ́n sì fi èdìdì meje dì í.

2 Mo sì rí angẹli alágbára kan tí ń ké pẹlu ohùn rara pé, “Ta ni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, ati láti tú èdìdì rẹ̀?”

3 Kò sí ẹnikẹ́ni ní ọ̀run, tabi lórí ilẹ̀ tabi nísàlẹ̀ ilẹ̀ tí ó lè ṣí ìwé náà tabi tí ó lè wò ó.

4 Mo sunkún lọpọlọpọ nítorí kò sí ẹnikẹ́ni tí ó yẹ láti ṣí ìwé náà ati láti wò ó.

5 Ọ̀kan ninu àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun yìí wá sọ fún mi pé, “Má sunkún mọ́! Wò ó! Kinniun ẹ̀yà Juda, ọmọ Dafidi, ti borí. Ó le ṣí ìwé náà ó sì le tú èdìdì meje tí a fi dì í.”

6 Mo bá rí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó dúró láàrin ìtẹ́ náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà yí i ká. Ọ̀dọ́ Aguntan náà dàbí ẹni pé wọ́n ti pa á. Ìwo meje ni ó ní ati ojú meje. Àwọn ojú meje yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje tí Ọlọrun rán sí gbogbo orílẹ̀ ayé.

7 Ọ̀dọ́ Aguntan náà bá wá, ó sì gba ìwé náà ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́.

8 Nígbà tí ó gbà á, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn mẹrinlelogun náà dojúbolẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan yìí. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú hapu kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́, ati àwo wúrà kéékèèké, tí ó kún fún turari. Turari yìí ni adura àwọn eniyan Ọlọrun, àwọn onigbagbọ.

9 Wọ́n wá ń kọ orin titun kan, pé,

“Ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ìwé náà,

ati láti tú èdìdì ara rẹ̀.

Nítorí wọ́n pa ọ́,

o sì ti fi ẹ̀jẹ̀ rẹ bá Ọlọrun ṣe ìràpadà eniyan,

láti inú gbogbo ẹ̀yà,

ati gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè.

10 O ti sọ wọ́n di ìjọba ti alufaa láti máa sin Ọlọrun wa.

Wọn yóo máa jọba ní ayé.”

11 Bí mo tí ń wò, mo gbọ́ ohùn ọpọlọpọ àwọn angẹli tí wọ́n yí ìtẹ́ náà ká ati àwọn ẹ̀dá alààyè ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Àwọn angẹli náà pọ̀ pupọ: ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun àìmọye.

12 Wọ́n ń kígbe pé,

“Ọ̀dọ́ Aguntan tí a ti pa ni ó tọ́ sí

láti gba agbára, ọrọ̀, ọgbọ́n, ipá, ọlá, ògo ati ìyìn.”

13 Mo bá tún gbọ́ tí gbogbo ẹ̀dá tí ó wà lọ́run ati ní orílẹ̀ ayé, ati nísàlẹ̀ ilẹ̀, ati lórí òkun, ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu òkun, ń wí pé,

“Ìyìn, ọlá, ògo, ati agbára ni ti ẹni

tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan lae ati laelae.”

14 Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá dáhùn pé, “Amin!” Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun.